Wahala laarin egbe awon dokita atijoba ipinle Osun gbona miin yo lopin ose to koja pelu bi agbarijopo egbe naa niha Iwo-Oorun Gusu orileede yii se so pe awon ti setan lati gbe peregi ija kana ti Gomina Aregbesola ko ba tete wa nnkan se soro won.
Lati odun to koja lawon dokita ti won n sise nileewosan to je tijoba ti bere iyanselodi latari airi owo osu won gba, se bii meji seyin lwawon dokita ti won je tijoba apapo naa dapo mo won lati fidii re mule pe awon setan lati ba awon akegbe won koya.
Opolopo ojo lo ti ro ti ile ti fa mu lorii wahala naa nitori pe awon araalu ko yee kerora inira ti iyanselodi awon dokitaa naa ti mu ba won.
Sugbon se nijoba ipinle Osun ni oun ko ni nnkankan toun le se lori oro naa ati pe iwon igba tawon gbe osise iyoku ti kowo bowe adehun lati maa bajoba farada wahala eo oro qje to n dojuko, o di dandan kaawon dokita naa gba kamu.
Koda, ijoba tun gbe iwe ipe sita pe enikeni to ba je akosemose dokita to si n wase le mu we wa sodo ijoba nitori pe awon ti fee gba awon dokita miin.
Gege bi Dokita Simeon Afolayan to je alaga igbimo tijoba gbe kale lati wa alaafia laarin ijoba atawon dokita se so, awon dokita naa ti huwa to lodi si alakale ofin ise labe ijoba to so pe osise to ba wose niran fosu meji gbodo mo pe ohun ti fowo ara oun ko iwe ifisesile.
Afolayan ni niwon igba tawon dokita to pe ni perete laarin awon osise ijoba ipinle Osun ti kuna lati pada senu ise, dokita tuntun bi merin lawon ti gba ninu ogunlogo awon dokita ti won ti muwe wa fun ise.
Sugbon egbe awon dokita nipinle Osun ni alawada bii Baba Sala ni Afolayan ati pe oun naa mo ohun to to, o kan kuna lati gbajoba nimoran daada ni.
Bakan naa ni agbarijopo egbe naa niha Iwo-Oorun Gusu orileede yii ninu atejade ti won fi sita so pe ijoba ipinle Osun kan n fi juuu bo awon eeyan loju n nipa owo to n wole latodo ijoba apapo, bee ni won ni Gomina Aregbesola ko so ooto nipa owo ibanuje to n san fawon osise.
Atejade naa eleyii ti Dokita Suraj Ogunyemi latipinle Osun, Dokita Olatunji M. B latipinle Oyo, Dokita Betiku O.B latipinle Ondo, Dokita Akinbote J.A. latipinle Ekiti ati Dokita Odewabi A.A. latipinle Ogun fowo si salaye pe lati nnkan odun 2012 lowo awondokita nipinle Osun ko ti loju, tijoba si n paro mo ijoba Jonathan.
Won ni o waa jo awon loju pe nigba tijoba miin tun de, ariwo ko sowo naa ni won npa, won ni o te awon osise ijoba yooku lorun ni lati maa fi ayo gba owo ibanuje tijoba n fun won, ati pe egbe awon dokia koo ni gba kijoba kankan fiya je omo egbe won.
Won waa ke si gbogbo awon araalu ti won mo oriki Gomina Aregbesola lato ba a soro lasiko ti yoo gbo nitori kesekese nijoba si n ri lodo awon dokita, kasakasa si n bo lona.
Wednesday, 24 February 2016
Awon dokita so pe alawada ni Gomina Aregbesola
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment