Tiyanutiyanu ni gbogbo awon eeyan ti won wa lagbegbe kootu majistreeti ilu Osogbo n wo ohun to sele lose to koja nigba ti okunrin Hausa kan tile ejo ju sewon osu mefa bu sekun ragbada lasiko ti won n gbe e lo sugbon ti hausa miin to n koja lo ba a sanwo itanran laitie mo on tele
Matireesi (matress) kan ti won ko lo mo, ti won si ju sita la gbo pe Abdullahi Kabiru ri, o si gbe e, sugbon kia ni won so ohun to se di ole jija mo on lowo ti won si fa a le awon olopa lowo.
Gege bi agbejoro funleese olopa lori oro naa, Inspekito Abiodun Fagboyinbo se so, iwa ti Kabiru omo odun mokandinlogun ohun hu naa lodi, o si nijiya labe ofin iwa odaran tipinle Osun.
Nigba ti akowe kootu ka awon esun ti won fi kan Kabiru sii leti, se lo bu sekun, o ni oun jebi esun naa ati pe se loun ro pe won ko lo matiresi naa mo nibi ti won ju u si toun fi gbe e lati maa fi sun ni toun.
Nigba to n gbe idajo re kale, onidajo majistreeti naa, Olusola Aluko pase pe ki okunrin hausa naa loo fi aso pempe roko oba fun osu mefa gbako tabi ko san egberun marun gege bii owo itanran.
Kabiru wo yikaa kiri kootu, ko ri eni to foju jo to le baa san owo itanran naa, lo ba tun bere sii wa ekun mu bii omi.
Ariwo ekun omokunrin yii tun po si nigba tawon woda so pe ko wonuu moto, ti won si n gbe e lo sogba ewon. Bi won se n lo lokunrin hausa kan to n koja gbo ede enu Kabiru, o si be awon woda lati mo nnkan to sele sii.
Nigba ti won so fun un pe airi egberun lona marun owo itanran san lo fee mu Kabiru loo gbategun logba ewon, o kowo bapo, o si ko egberun marun naira jade. Bayii ni won pada si kootu, ti won si yanju oro Kabiru, to si gba ominira lojo naa.

No comments:
Post a Comment