Ogbeni Gbenga Iyanda ti ro ile ejo koko-koko kan nilu Osogbo
lati ba oun gba awon omo oun mejeeji lowo iyawo toun fe tele nitori won ko ritoju to peye lodoo re.
Gege bi omokunrin naa se wi, leyin tawon bimo meji funra awon nigbeyawo naa fori sanpon, ti awon omo naa; Iyanda Abdulraman omo odun mejo ati Nimota Iyanda toun je omo odun marun bayii ti bere sii gbe lodo iyaa won, ti oun naa si ti feyawo miin.
O fi kun oro re pe oun pinnu bayii lati gba awon omo oun mejeeji lowoo Sakirat Sulaiman nitori ojo iwaju awon omo naa se pataki foun.
O fesun kan Sakirat pe o n seranu kaakiri, bee ni ko raaye mojuto awon omo naa lati fun won ni eko gege bii obinrin. O ni opo igba loun gbo pe Sakira yoo ti awon omo naa monu ile to ba n tele awon orekunrin re jade lo.
Gbenga ni gbogbo iwa Saki yii lo n mu ki ina eto eko awon omo oun mejeeji naa jo ajoreyin lojoojumo eleyii to ni ko dun mo oun ninu to si mu ki oun pinnu lati waa gba awon omo oun ki ayee won ma baa baje lowo iyaa won.
Sugbon Saki ni tie ni awijare lasan ni gbogbo atotonu Gbenga nitori pe bi igbeyawo aarin awon se tuka laaro ojo lo fa akude to de ba eto eko awon omo naa.
Saki ni oun ko setan lati ko awon omo naa sile nitori oun ko le gba ki enikeni gba ise oun se nigba toun si wa laaye.
Ninu idajo aare kootu naa, Oloye N.L. Odelola pase pe ki Saki yonda Abdulraman toun je omo odun mejo fun baba omo. O si fun won lojo ti Saki gbodo mu omo naa wa sile ejo ki baba re le maa mu un lo.

No comments:
Post a Comment