Iyawo ile kan, Arabinrin Tejumola Abidemi ti ke gbajare lo siwaju kootu koko-koko kan nilu Osogbo pe ki won tu igbeyawo olodun marun to wa laarin oun ati oko re, Tejumola Ganiyu ka.
Esun ti obinrin onisowo yii fi kan oko re ni pe alagbere ni bee ni iwa yii ko je ko raaye toju oun atawon omo meji to wa ninu igbeyawo naa rara.
Abidemi ni omuti paraku to tun n fa siga loko oun, to si je pe to ba ti muti yo bayii ni yoo so oun di boolu alafesegba sinu ile, ti yoo si fee fi lilu yin oun lorun.
O ni "To ba ti muti yo, se ni yoo ti mi monu ile leyin to ba na mi tan, ti yoo si jade lo ni tie, kii bikita rara femi atawon omo mi mejeeji. Emi niyawo keta to fe, emi nikan naa ni mo si n gbenu ile pelu e nitori awon iyawo to ku ti ko jade tipe.
"Nitori pe mo je omo orukan ti mo si nilo eni ti yoo maa tojuu mi ni mo se fe e, bo tile je pe o n tojuu mi loooto nitori o lowo lowo sugbon ko ni aaye fun emi atawon omo mi.
"Iya lo fi maa n je mi nigbakuugba to ba ti muti yo, koda, ese lo fi yo eyin mi danu lasiko ija kan ti a ja gbeyin, n ko le kaye igba ti mo ti loo ti ejo re sun awon obi e sugbon ti ko yipada, idi niyen ti mo fi fe ko o sile."
Bo tile je pe Ogbeni Tejumola Ganiyu ko wa sile ejo lati wi awijare tire lori awon esun tiyawo re fi kan an, sibe o ranse si kootu pe oun gan an ti setan lati ko iyawo oun, o si ni kile ejo tu awon ka.
Ninu idajo re, aare kootu naa, Oloye Nasiru Odelola pase pe ki igbeyawo naa di tituka loju ese ati pe ile ejo ni yoo je alagata laarin awon mejeeji ti won ba fee beere nnkan kan lowo araa won.

No comments:
Post a Comment