IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 30 March 2016

Dauda to n tun redio se gan mona l'Osogbo

Bii igba tawon Aafa Sule n korin "o ti gan pa"lawon eeyan agbegbe Odeyemi
ni Kolawole nilu Osogbo n wo lose to koja nigba ti omokunrin kan dede dake lori opo ina to ti n so waya papo sugbon nigba to di pe ko tete mira mo ni won figbe ta.
Redio la gbo pe Ismaheel Dauda n tun se lagbegbe naa, sugbon igbakuugba ti ina ijoba ba ti yonu lori opo ni won maa n ranse sii ni soobu re to si maa n ba won se e.
Bii eni pe ara ti n ro ajalu fun un lojo naa ni nitori nigba ti ore re kan koko loo pe e wipe ko waa ba won so ina tawon ajo IBEDC, a gbo pe se ni Dauda koko yari pe oun ko se.
Sugbon nigba ti ebe po, o gba lati ba won se, bee la gbo pe o loo wa akaba onirin kan to fi gun opo ina ohun.
Ko tii ju iseju marun to gun opo naa ti ina fi gbe e sugbon awon ti won wa layika ibe ko tete mo, se ni won kan n fokan sii pe Dauda n sie lo lara opo ina ni.
Ason kan ti won n muti lagbegbe ohun ti won n wo nnkan to n sele lookan la gbo pe won sakiyesi pe okunrin naa ko minra lori opo ina to wa, bayii ni won sunmo ibe ti won si rii pe ina ti gbe e.
Gbogbo won bere sii mi opo ina naa ti ti Dauda fi jabo lu garawa kan to wa legbe opo ina naa ko too jabo sileele.
Nigba to n fi aidunnu re han si isele buruku ohun, agbenuso funleese apinna IBEDC, Kike Owoeye ni o seni laanu pe pelu gbogbo ariwo ati ikilo ti ajo naa n pa pe ki enikeni ti ko ba mo nipa ina mase maa sunmo opo ina sibe awon eeyan kan si n femi araa won wewu.
O waa ro awon eeyan ipinle Osun lati jawo ninuu fifowokan dukia ajo IBEDC lati le yago fun akoba to le tipasee bee waye nigbakuugba.

No comments:

Post a Comment