IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 30 March 2016

E gba mi lowo iyawo mi o, se lo so pe oun yoo so mi di dindinrin -Rafiu


Se ni gbogbo awon ti won wa ni kootu ibile keji nilu Osogbo n woju araa won lasiko ti okunrin kan, Bakare Rafiu n so niwaju awon adajo pe ki won tete ba oun tu igbeyawo oun pelu Bakare Kehinde ka ko too di pe obinrin naa yoo so oun di dindinrin gege bo se n leri.
Ogbeni Rafiu ni ailalaafia ninu ile loun koko n dojuko latodo iyawo oun toun fe lati odun mesan seyin ko toodi pe o tun bere sii leri kaakiri pe oun yoo so oun di dindinrin patapata.
O ni yato si eleyii, alarifin niyawo oun ti ko niteriba fun enikeni, koda kii fojuure wo awon obi oun to si je pe epe lo fi maa n ranse si won ni gbogbo igba.
Gege bi okunrin to n sise dereba yii se wi "se ni mo sa kuro ninu ile nigba to di pe o nleri lati so mi di dindinrin, inuu soobu booda mi ni mo n sun bayii, sibe ko tun je ki n sinmi.
"Gbogbo igba lo wa maa n ba mi ja nibe, se lo tun leri pe oun yoo ba boosi ti mo fi n sise je lojo to wa gbeyin, e dakun e gba mi lowo e o".
Nigba ti won beere ohun tiyawo okunrin yii ri to fi waaro owo, se ni Kehinde ni ko si iro ninuu gbogbo nnkan ti oko oun so rara.
O ni "loooto ni mo hale mo on, bee ni mo gbe awon obi e sepe sugbon oun lo fa gbogbo e. Laipe yii lo so fun mi pe ki n loo se oyun kan to fee gba emii mi, sugbon iyalenu lo je fun mi pe se lo pa mi ti si osibitu, ko de odo mi rara.
"Ti kii baa se ti aburo mi to tojuu mi nileewosan boya oro iba ti yiwo fun mi bayii, ijeta ni mo sese dele lati ileewosan sugbon iwe ikosile re lati kootu lo fi ki mi kaabo."
Leyin eyi ni obinrin yii waa so funle ejo pe oun naa ko fe oko yen mo ati pe oun faramo on ki won tu igbeyawo naa ka.
Leyin ti awon adajo kootu naa ti rii pe ko si ife mo laarin awon lokolaya naa, aare won, Oloye Bolarinwa pase pe ki won maa lo lotooto leyin ti o tu igbeyawo naa ka.

No comments:

Post a Comment