Adajo majistreeti kan nilu Ileefe ti pase pe ki won fi obinrin eni odun merindinlogota kan, Funmilola Babalola pamo sogba ewon ilu Ilesa titi ti agbejoro re yoo fi seto ohun gbogbo to nilo fun beeli re.
Esun ti won fi kan obinrin yii ni wipe o mu omo olomo kan lo silu Eko laigba ase ati iyonda awon obi omo yii lati se bee.
Gege bi agbejoro funleese olopa lori oro yii, Sajenti Monday Oseijele se so, lojo kejo osu keta odun yii ni Arabinrin Funmilola mu Nafisat Suleiman lo lona aito.
Oseijele ni iwa ti olujejo ohun hu lodi si abala kan ninu ofin iwa odaran ti odun 2002 tipinle Osun.
Nigba ti won ka esun iwa mimu omo lona aito ti won fi kan obinrin yii sii leti, o ni oun ko jebi.
Agbejoro olujejo, Ogbeni Ben Adirieje ro ile ejo lati faaye beeli sile fun olujejo lona irorun, o ni o setan lati fi awon oniduro ti won loruko sile ati wipe ko nii salo fun igbejo rara.
Nigba to n gbe idajo re kale, Majistreeti Iyabode Salani faaye beeli sile fun olujejo pelu egberun lona marundinlogorin ati oniduro kan ni iye kannaa.
O ni oniduro yii gbodo je osise ijoba ipinle to wa nipele karun, o si gbodo fi iwe eri owo ori olodun meta sile.
Leyin eyi lo waa pase pe ki won loo fi olujejo pamo sogba ewon ilu Ilesa titi ti ohun gbogbo to nilo fun beeli re yoo fi pe.

No comments:
Post a Comment