Latari bi gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola se kede idasile kansu Ila-Oorun Ariwa Ife eleyii to fibujoko re silu Modakeke lose to koja lohun, awon eeyan ilu naa ti so pe gboingboin lawon wa leyin isejoba naa lojokojo.
Asaaju awujo kan to tun je adari fegbe oselu APC nilu naa, Alhaji Oloye Wahab Adetunji
ti gbogbo eeyan mo si Olowo-Asalu lo soro yii fun Alaroye lasiko to n fidunnu re han sigbese gomina ohun.
Alhaji Adetunji ni ohun ti opolopo emi ti lo si, ti dukia ainiye si ti para si ni Gomina Aregbesola se funlu Modakeke lojo naa.
Ti e ko ba gbagbe, losu kejo odun 1997 ni gomina ologun nipinle Osun nigba naa, Uzoma Obi kede idasile ijoba ibile Ila-Oorun Ife, o si fi ibujoko re si Oke D.O. nilu Modakeke, sugbon lojiji nijoba tun kede laarin ojo melo kan siraa won pe kibujoko kansu naa maa lo si Oke-Ogbo nilu Ileefe.
Eleyii lo fa wahala to fi odidi odun merin waye laarin awon eeyan ilu Modakeke ati Ife, to si je pe apa ogun naa ko kuro lara ilu mejeeji doni-oloni. Ohun to dawoo wahala naa duro nigba naa ni bi Aare Olusegun Obasanjo se so pe kijoba Gomina Adebisi Akande fun Modakeke ni Eeria-ofiisi, ti won si n je Ife East Area Office latigba naa. Ohun ti eleyii tumo si ni wipe bijoba ba fun ijoba ibile Ila-Oorun Ife ni nnkan mewa, awon ti Oke-Ogbo yoo gba meje, nigba ti awon Modakeke yoo gba meta.
Sugbon se ni gbogbo awon omo ilu naa nile-loko fon si ojuutiti, ti won si n dawo idunnu lorii ikede ti Gomina Aregbesola se lose to koja lohun pe ilu naa ti dibujoko odidi kansu to pe ni Ijoba ibile ila-oorun ariwa Ife (Ife North East).
Bo tile je pe nnkan ko rosomu funjoba ipinle Osun lasiko yii lati le ro owo sawon ijoba ibile latari bi owo epo torileede yii gbojule se ja gbogbo won nitannmo, sibe awon eeyan ilu Modakeke so pe ilana kolomu da omu iyaa re gbe (parliamentary system of government) ti Gomina Aregbesola kede te awon lorun.
Bakan naa, Alagba Bisiriyu Kolawole ni tie so pe igbese gomina naa je eyi to wuyi pupo ti yoo si fun awon eeyan ilu Modakeke lanfaani lati gbajumo igbese idagbasoke ilu naa.
Won waa dupe lowoo Aregbesola, bee ni won gbosuba fun Ooni Enitan Ogunwusi ati Oba Francis Adedoyin fun aseyori naa.
Wednesday, 23 March 2016
Nitori idasile kansu; awon eeyan Modakeke seleri atileyin funjoba Aregbesola
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)



No comments:
Post a Comment