Oro di wo-mi-n-wo oni kootu koko-koko to wa ni Oja-Oba nilu Osogbo laipe yii nigba ti omo odun meje kan so pe odo iya oun loun yoo maa gbe leyin tile ejo ti tu igbeyawo awon obi e ka.
Eemeta otooto lawon adajo beere lowo omodekunrin naa, Micheal Dada pe odo taa lo nife si lati maa gbe laarin iya ati baba e, sugbon se lo so pelu igboya si iyalenu baba re pe odo iya oun loun fee maa gbe.
Ogbeni Alaba Dada lo to ile ejo lo pe ki won tu igbeyawo olodun mewa to wa laarin oun atiyawo re, Aina Dada ka lori esun pe onidoti ati oniwahala lobinrin naa.
Okunrin yii ni oun ko ni alaafia latigba toun ti fe Aina ati pe kii setoju oun atawon omo to bi fun oun. Bakan naa ni okunrin yii ro ile ejo lati pase pe ki oun mu akobi awon, Micheal sodo funtoju.
Sugbon iyawo okunrin yii ni iro funfun balau ni gbogbo esun ti oko oun fi kan oun, o ni se ni oko oun pa ojuse re ti ti ko si setojuoun atawon omo.
Obinrin yii ni oun naa faramo on kile ejo tu igbeyawo naa ka sugbon ki won je ki Micheal maa gbe lodo oun ko le nitoju to peye.
Niwon igba to si je pe omo naa kii se omokekere, awon adajo kootu naa pe Micheal siwaju pe ko waa so eni to fe lati maa gbe lodo e laarin awon mejeeji.
Sugbon se ni baba Micheal di owo mori nigba ti Micheal so nigba meta otooto pe odo iya oun loun fee maa gbe
Leyin eyi ni aare kootu naa, Oloye Bolarinwa Popoola tu igbeyawo naa ka, o si pase pe ki Micheal maa gbe odo iya e sugbon ko maa fun baba re lanfaani lati ri omo re nigbakuugba to ba fee rii.
Thursday, 14 April 2016
Leyin tigbeyawo olodun mewa tuka l'Osogbo, omo ni odo iya oun loun fee maa gbe
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment