IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 12 April 2016

Won ge eya ara oku Iya Adua lo losibitu Tinu-Ola l'Osogbo


Titi di igba ti a n koroyin yii jo, inuu hilahilo ni dokita to nileewosan Tinu-Ola Clinic & Maternity Centre to wa ni No 2, opopona Bishop lagbegbe Olu-Ode nilu Osogbo wa lori esun pe awon eya ara iya kan to ku sosibitu naa dawati.
Gege bi Alaroye se sewadi, ale ojoo Wesde to koja ni iya naa, Iyaafin Afusatu Sakariyau ti gbogbo eeyan mo si Iya Adua dede n pariwo pe aya n dun oun, niwon igba ti ko si si ikankan ninu awon omo meteeta to bi nitosi lasiko yen, lawon araale re ba gbe e lo sileewosan Tinu Ola.
Nigba ti won gbe iya yii debe ni nnkan aago mesan ale ni won loo pe abikeyin re, Iqmah (Ikimoh) ti iyen naa si ranse si awon egbon re mejeeji to ku.
Okan lara awon omo mama yii, Waliyat Raji so pe nigba toun fi maa debe ni nnkan aago mokanla ale, elemi ti gba a lenu iya naa, leyin toun si kiyesi pe iya oun ti dake loun fowo wo o loju wale, ibe loun si wa ti akobi iya naa fi de pelu oree re kan to je aafa.
O ni gbogbo eleyii ti n di nnkan aago mejila aabo, oun si so fun egbon oun pe oun fee maa lo sile.
O salaye siwaju pe "Nigba ti mo fee kuro nibe, egbon mi so pe awon pelu ore awon maa sun sorii beedi to wa legbe ibi ti won te mama mi si titi ti ile fi maa mo, a si dagbere funraa wa. Sugbon nigba to fi maa di aago meta aabo idaji ojoo Tosde, egbon mi waa kanlekun ilee wa, won so fun mi pe iya mi yo sawon loju oorun pe ara ni awon nibi tawon wa.
"Mo beere pe sebi osibitu ni won sun, egbon mi ni rara ati pe bi gbogbo wa se kuro nibe ni baba kan to pe araa re ni dokita nigba ti a debe pelu awon noosi ti won wa nibe atiyawo okunrin to ni osibitu yen gan an gan so pe kawon bo sita ati pe se ni kawon pada wa nidaji kile too mo daada, ti won si tilekun osibitu pa.
"Bayii ni emi ategbon mi pelu oree won atawon araale wa kookan gbera, o di osibitu yen sugbon ohun ti a koko kiyesi ni pe bi won se te mama mi loru ka too kuro nibe yato si bi a se ba won nidaji yen.
"Egbon mi loo si aso kuro lojuu won sugbon iyalenu ni nnkan ti a ba je. Won ti fi nnkan kan bii sisoosi re abala imu won kan, won ge lara ete won, bee ni oju apa wa legbe ojuu won loke, koda, a ba abere kan legbe beedi wonti won ti lo.
"Egbon mi pariwo sita pe ki lo sele si mama wa ati pe awon ko nii gba o, sugbon se ni baba to pe araa re ni dokita yen so pe eku lo je awon eya ara ti a ko ri yen, oro yii di ariwo ti gbogbo awon araadugbo yen gbo, a si loo fi to awon olopa Dugbe leti.
"Koda, awon odo adugbo naa tinu n bi yari pe awon yoo ba ileewosan naa je, bee lawon kan so pe se lawon maa dana sun un sugbon se la n parowa si won pe ki won se suuru ki oro naa baa le loju".
Bakan naa ni Iqimoh to n gbe pelu iyaa re salaye pe awon jo je moinmoin ati eko ni lale ojo naa, ti iya naa si sanra ko too di wi pe oun jade kuro ninu ile lo sodo enikan ti won ran oun si. O ni latibi ti oun lo loun ti n bo tawon araale pade oun pe won ti gbe iya oun lo sileewosan yen.
Alaroye sabewo si Ile Baba Onikeke lagboole Olobu loja Oluode nibi ti Iya Adua n gbe nigba ayee won, gbogbo won ni won si so pe oninuure niya eleko ati pe eni to lesin ni iya naa to le die ni aadota odun naa.
Bakan naa, ni ile baba to bi Iya Adua ni Ile Oluawo nilu Osogbo, se lawon eeyan n lo sibe pelu eri pe iya naa sin Olorun nigba ayee re. Koda, gbogbo awon ijo Thidjania ti won maa n se ijoko Wasifa ati Wubura lodi Iya Adua ni won n wo loo ki won nibe.
Ni bayii, ejo naa ti wa nileese to n wadi iwa odaran nilu Osogbo, bakan naa ni olopa kan to ni ka foruko bo oun lasiri so pe won ti n gbe igbese lati sayewo si oku iya naa lati le mo ohun to sele gan an.
Leyin eyi ni won yoo gbe oku iya Adua lo si Ile Petu-Okeela nilu Erin Osun tii se ile okoo re nibi ti won yoo sin in si.

No comments:

Post a Comment