Egbe akekojade ni OAU seleri atileyin fun adele giwa tuntun
Agbarijopo egbe awon akekojade ti Obafemi Awolowo nilu Ileefe ti jeje atileyin won fun adele giwa ti won sese yan funleewe ohun, Ojogbon Adebola Elujoba.
Bakan naa ni won gbe osuba kare funjoba apapo orileede yii fun igbese akin to gbe lati rii pe wahala to waye lasiko yiyan giwa tuntun funleewe naa.
Ninu atejade ti egbe naa fi sita nipase aare gbogbogbo won, Ogbeni Segun Oke lo ti so pe gboingboin lawon wa leyin Elujoba nitori onilu kii fe ko tu ati pe nigba ti alaafia ba wa ni OAU legbe akekojade yoo wa ni alaafia.
Oke ni nnkan iwuri ni igbese ijoba apapo eleyii to ni o bo sasiko ati pe o mu iberu kuro lokan awon oluko anti akeko ileewe naa.
O ni iwadi nipa iru eni ti Elujoba je to fidii re mule pe alaseyori ti igba ati akooko re yoo mu ilosiwaju ti ko legbe ba ileewe naa ni.
Oke ni ohun ti egbe naa wa fun ni bi itesiwaju yoo se maa ba tolori telemu logba naa ati pe awon ko gbe si enikeni leyin rara.
O waa ro gbogbo awon ti won si ni ikunsinu kan tabi omiin lati fowowonu ki won si gbaruku ti Ojogbon Elujoba fun idagbasoke ileewe naa.
Wednesday, 3 August 2016
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment