Bi wiwa aare orileede yii, Alhaji Mohammodu Buhari sipinle Osun se ni ire to mu lowo fawon kan bee naa lo ni idakejii re fawon miin, sugbon ni ti aya gomina ipinle Osun, Alhaja Sherifatu Aregbesola, o ti jewo gbangba pe ojo ti aare wa ohun ni inu oko oun dun julo ri laye.
Alhaja Aregbesola so yanya lojo keji ti aare wa pe oun ko mo bi oun se le salaye oro naa fawon oniroyin sugbon nnkan kekere toun le so ni wipe ojo yen lojo akooko toun yoo ri ki inu oko oun dun julo ri laye.
Iyalenu loro naa je fun gbogbo awon ti won gbo o nitori aimoye ojo ni Gomina Aregbesola atiyawo re yoo ti jo lawon aseyori ti yoo mu idunnu wa sugbon aya gomina ni oun ko tii rii ki inu oko oun dun to bee ri laye.
Nitoooto, erin ni Gomina Aregbesola nrin saa fun wakati bii marun ti Aare Buhari lo l'Osogbo lojo naa. Ileewe Osogbo Government Grammar School to wa loju ona Iwo si Ibadan ni Aare waa si ni won koko forile. Leyin ti aare ye awon kilaasi ikekoo to wa nileewe naa wo ni won koja sibi gbongan igbalejo.
Ninu oro ikinni ku aabo re, Gomina Aregbesola ni aseyori tijoba oun se lori awon ileewe ayagbayamuyamu naa ko seyin ipinnu ati ife toun ni si idagbasoke eto eko nipinle Osun.
Arebesola nibo tile je pe oda owo tii se awo olokun pa opolopo ara mo oun ninu, sibe pelu ifowosowopo awon eleyinju aanu kaakiri agbaye, oun ti gbe eto eko soke tente nipinle Osun.
O waa dupe lowo Aare Buhari fun atileyin re paapa pelu bo se fi wiwaa re sipinle Osun ye oun si. O ni aare ko ja egbe awon kule rara nitori pe bi awon se fe ki nnkan ri naa lo se n ri werewere.
Ninu oro tire, Aare Buhari ni se ni kawon araalu ni suuru fun egbe awon o nitori pe ayipada kii se nnkan to maa n waye lojo kansoso, ohun to gba suuru daada ni.
Buhari ni tita- riro laa kola, nigba to ba jinna tan lo maa n doge, o ni ijiya isinsinyii ko see sakawe ogo to n bo wa fawon omo orileede Naijiria ati pe egbe APC yoo gbe won debute ayo.
O waa gboriyin fun Gomina Aregbesola fun isejoba re nipinle Osun, bee lo ki awon araalu fun ifowosowopo won.
Amo sa, pupo ninu awon oloja nilu Osogbo, paapa awon ti won n ta worobo lagbegbe Olaiya si Oke Fia ni inu won ko dun lojo naa rara. Nigba to ti ku ola ti aare yoo wa ni won ti wo gbogbo soobu kekeke ti won fi n ta worobo won legbeegbe titi.
Okan laraa won to ba Alaroye soro sugbon to ni ka foruko bo oun lasiri so pe ireti oun nipa abewo aare naa ja sofo patapata.
O ni "latigba ti mo ti gbo pe aare nbo ni inu mi ti n dn, koda mo ti sare loo yawo ra awon nnkan ate ti mo n ta, mo mo pe awon oloselu yoo wa latibi gbogbo waa wo aare, sugbon se ni won le wa danu nibi ti a n duro si, ti won si wo soobu wa lule".
Wednesday, 7 September 2016
Abewo Aare Buhari lo mu inu oko mi dun julo ri fungba akooko - Iyawo Aregbesola
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment