IROYIN YAJOYAJO

Monday, 5 September 2016

Awon odo ilu Esa-Oke na osise IBEDC, ni won ba ju won sinu okunkun biribiri


Afaimo ni ko nii pe die ki awon eeyan ilu Esa-oke nijoba ibile Oriade nipinle Osun too gburo ina monamona peluu bi won se dana iya fun meta ninu awon osise ajo apinna to n je Ibadan Electricity Distribution Company (IBEDC).
Ohun ti a gbo ni pe ajo to n funna lagbara latilu Osogbo, Transmission Company of Nigeria (TCN) fee satunse sawon ina ijoba lagbegbe naa, idi si niyii ti won ko fi ni ina laarin ogunjo osu kejo odun yii si ojo kejilelogun.
Sugbon kaka kawon eeyan ilu ohun farabale loo beere ohun to sele si ina won lodo awon osise IBEDC nilu naa, se ni won ki awonosise ohun mole ti won si na won bii eni na bara.
Gege bi alukooro ajo IBEDC, Kikelomo Owoeye se salaye, falafala lara awon osise meteeta naa bo, bee lawon odo ilu naa tun ba opolopo nnkan je lofiisi won lojo naa.
Owoeye ni ohun to tun waa mu koro naa lagbara ni pe ko tii pe rara ti gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ba awon eeyan ohun bebe lodo ajo IBEDC leyin ti won ti fi opolopo osu wa ninu okunkun latari pe won hu iru iwa ti won hu yii.
O ni oniruuru ona lajo naa ti la sile lati maa ba awon araalu soro lori ohunkohun to ba ru won loju sugbon to ni awon eeyan ohun ko besubegba ti won fi koju ija sawon osise IBEDC.
Owoeye fi kun oro re pe kii se ajo IBEDC lo fa a ti won ko fi ri ina lo lasiko yen, awon ajo TCN ti won fe fun awon ina kan lagbara ni won pa ina.
O waa ro awon araalu lati ri awon osise IBEDC gege bi ore ati alabasoropo, ki isee won ba le rorun ati ki awon araalu le maa jegbadun ina ijoba loorekoore.

No comments:

Post a Comment