IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 8 September 2016

Awon osise OAU tilekun mo awon logaloga soofiisi

Awada lawon logaloga nileewe Obafemi Awolowo University to wa nilu Ileefe koko pe oro naa lojo Aje to koja lohun, sugbon nigba ti won ri oogun abenugongo, se lonikaluku won juba ehoro.
Awon osise ileese naa ni won koraa won jo, ti won di enu ona abawole ni ofiisi nla ti won n pe ni Senate Building, ofiisi yii ni akowe agba ileewe naa( Registrar) ati akowe owo (Bursar) wa.
Se ni won ni won gbo finrinfinrin pe akowe owo ohun ti ko iwe sowedowo onimilioonu lona ogbon naira sile eleyii ti won fee fun oga agba ileewe ohun to feyinti pelu irukerudo laipe yii, Ojogbon Bantale Omole.
Bayii lawon osise naa se oro naa ni enu eni la fi maa nko meeje, won gbe iwe ehou, won ko oogun atawon nnkan miin lo sibe pe obitibiti owo ajemonu wanile ti Bantale ko je kawon ri gba titi to fi lo, ki lo waa de to je pe owoo tie ni won kokofee yanju.
Awon osise yii ni kaka keku ma je sese lawon yoo fi oro ohun se nitori aimoye igba lawon ti loo ba akowe owo naa nipa owo awon sugbon ton so fawon pe ko tii sowo nile, won ni nibo waa ni milioonu lona ogbon ti won fee san fun Bamtale ti jade wa.
Awon osise ohun ni awon logaloga ro wipe awon ko nii gbo ohun ti won fee se, won ni tojutiye laparo awon fi n riran bayii nitori iya tawon je labe isakoso Ojogbon Bamtale ko tun gbodo je awon mo ati pe bi awon se reni ta awon lolobo igbese akowe owo naa lawon ti kede laarn ara awon.
Leyin ti oro naa di ariwo, adele oga agba ileewe naa ba alaga egbe awon osise ibe, Comreedi Wole Odewunmi soro, o si ba a sadehun pe logan lawon yoo bere igbese lati san owo ajemonu ti won je awon osise.
Sugbon se lawon osise ohun tun ho le alaga won lori nigba to fun won lesi ipade to ba awon alase se, won ni se ni ko pada loo beere ojo ti won yoo bere owo ohun ni sisan gan an nitori aja to yo ko lee ba aiyo sere rara.
Nigba ti awon alase rii wipe awon osise ohun ko mu oro naa ni seresere rara, adele giwa ileewe naa, Ojogbon Anthony Elujoba jade sita waa ba awon osise ohun soro, o si seleri lati rii pe gbogbo eto won di sisan laipe rara.

No comments:

Post a Comment