Sebi won ni owo to ba n dunni, a kii fi sabe aso, idi niyii tawon omo
ile igbimo asofin ipinle Osun fi pariwo sita lose to koja pe iya to
koja eyi ti Judasi je lo n je awon lowolowo bayii pelu wahala ti eto
oro aje ko ba won.
Igbakeji abenugan ile, Onorebu Akintunde Adegboye lo soro yii fawon
oniroyin nilu Osogbo. O ni oro naa kojaa maje-a-gbo nitori pe aisi owo
ti so gbogbo awon asofin di ahun lodo awon molebi atawon osise ile
igbimo asofin gan an papa.
Adegboye ni opolopo ojo lawon maa n sun ninu okunkun nileegbe awon
asofin nigba to je pe obitibiti lowo ina tawon je, bee lo je pe lati
se ohun to to fawon araalu ti won dibo yan awon tun ti dogun bayii.
O fi kun oro re pe lati ra epo petyiroolu sinuu jenereto tun di wahala
lopo igba ati pe moto onikaluku won ni won n lo kaakiri bayii nigba ti
ko si owo lati ra moto to je tawon asofin.
O ni opo awon alaini atawon odo ti won ko tii rise gidi se tawon maa n
ran lowo tele ni won ti n fi oju ahun ati alainikanse wo awon bayii
sugbon ti won ko mo pe adiye n laagun, iye ni ko je.
O ni bi won se n pariwo pea won kan towo bo iwe isuna orileede yii ko
lee sele bee nipinle kaakiri nitori pe lati san owo osu awon osise
lawon gomina naa n gbajumo lowo.
Sugbon alaga egbe oselu APC nipinle Osun, Omooba Gboyega Famoodun ti
so fawon asofin naa pe se ni ki won maa farada iya to n je won o ati
pe ko gbodo han lojuu won kawon araalu ma baa maa so nnkan miin.
Famoodun ni eto oro aje to denukole lorinleede agbaye lo fa wahala naa
ati pe ijoba Buhari n sa gbogbo ona lati mu orileede yii bo sipo
eleyii to nii yoo so eso rere laipe.

No comments:
Post a Comment