Ase loooto ni wipe ojo gbogbo ni tole, ojo kansoso ni ti olohun, ojo ti pe ti obinrin eni odun metadinlogbon kan ti n lu awon onisowo inu Oja Tuntun nilu Ileefe ni jibiti, sugbon owoo palaba re ti segi bayii.
A gbo pe se ni obinrin naa Atinuke Olawoyin loo se kaadi idanimo banki alabode kan niku Ileefe ti won n pe ni Olofin Microfinance Bank, bee lo tun se ayederu awon orisiirisii eleyii ti yoo mu ko soro fun enikeni lati so pe kii se banki naa lo ti wa.
Ayinuke fori le inu oja, o si bere sii gba ajo ojoojumo lowo awon onisowo leyin to ba ti pe araa re ni okan lara awon osise ileefowopamo naa to wa lagbegbe Moore nilu Ileefe..
Sajenti Sunday Osanyintuyi salaye pe lojo kerindinlogun osu kesan odun yii ni asiri Atinuke tu ni nnkan aago mokanla aabo aaro.
Osanyintuyi ni iwa ti Atinuke hu ohun lodi si ofin iwa odaran tipinle Osun bee lo si ni ijiya pupo.
Agbejoro fun.olujejo, Ogbeni Martins Awe ro ile ejo lati fun oun lanfaani lati gba beeli olujejopelu ileri pe ko nii salo fun igbejo.
Arabinrin Iyabo Salami to je adajo mejistreeti naa faaye beeli sile fun un pelu egberun lona ogorun naira ati oniduro kan ni iye kannaa.
O ni oniduro naa gbodo ni iwe eri owo ori olodn meta, bee ni ki beeliifu kootu mo adiresi ilee re.
Salami wa sun igbejo siwaju di ojo kejidinlogun osu kewa odun yii.

No comments:
Post a Comment