IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 15 September 2016

Kukah so'ko oro ranse si Aare Buhari, o ni eyi to saroye ti to gee

Bisoobu ijo Katoliiki ti agbegbe Sokoto, Mattew Hassan Kukah ti so pe se ni ki Aare Buhari gbaju mo imuse awon ileri to se fawon eeyan orileede yii lasiko to n sepolongo ibo, dipoo ko maa fojoojumo saroye lori oro isejoba Goodluck Jonathan.
Kukah soro yii nilu Akure lasiko ipade awon bisoobu ijo Katoliiki lorileede Naijiria to waye nibe. O ni ireti awon eeyan po lorii Buhari ju ejo asise Jonathan toun atawon isomogbe re n fojoojumo ro lo.
Iranse Olorun yii ni ki nnkan ma baa baje ju bo se wa lo lawon eeyan se dibo yan Buhari to selerii iyipada sugbon o je iyalenu pe aroye ni saa lojoojumo.
O ni kii se oro wiwoya ija peluu iwa ibaje nikan bi ko se ko wa ona ti ara yoo fi tu awon eeyan.

No comments:

Post a Comment