Owo ileese olopa ipinle Osun ti eka Ileefe ti te okunrin kan, Ebun Akinnawonu omo odun mejilelogoji, eni to wa latilu Ore nipinle Ondo waa jale nilu Ileefe.
O ti koko ji owo to to egberun lona mejidinlaadota naira ninuu soonu Abudulazeez Yakubu lagbegbe Olu-Ere nilu Ileefe lojo kejidinlogbon osu kejo odun yii ni nnkan aago merin irole ti owo ko te e, sugbon owoo palaba re segi lojo kefa osu kesan odun yii.
Se la gbo pe Ebun tun tunramu, o forile agbegbe Fajuyi nilu Ileefe yii kanna ni nnkan aago kan aabo osan, o fogbon wonuu soobu okunrin kan to n je Nwafor Sunday pelu ipnnu lati jale bii isee re.
Sugbon bo se fee mowo naa ni akara tu sepo, ti asiri Ebuun si tu ko too di wipe o ri owo naa ji.
Agbenuso funleese olopa lori oro naa, Sunday Osanyintuyi ni oluejo naa ko daamu awon olopa rara to ti jewo pe loooto loun huwa naa nitori pe nibi to ti fee se e gan lowo ti te e.
Osanyintuyi ni iwa to hu ohun lod si ofin iwa odaran ipinle Osun, bee lo si nijiya labala ikerinlelogbon iwe ofin ohun.
Nigba to n gbe idajo re kale, Majistreeti Iyabo Salami so pe ohun ko lee sij aanu wo Ebun rara nitori pe opolopo awon eeyan laye ode oni ni won ko setan lati ni suuru rara.
Adajo naa ni dipo ki won fowo sise ti yoo mu won di oloro, ere ola oojo ni won a maa sa, bee ni won yoo maa huwa ti yoo ba oruko won je kaakiri.
O waa pase pe ki olujejo loo maa naju logba ewon fun odidi osu mejila tii se odun kan gbako ko baa le je eko fawon odo alapamasise to ku.
Tuesday, 20 September 2016
Latilu Ore ni Ebun ti waa jale n'Ileefe, adajo ti juu sewon odun kan
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment