Omokunrin dereba kan, Abioye Olufemi eni odun mokanlelogbon yi foju bale ejo majistreeti ilu Osogbo lori esun pe oun atawon ore re na olopa to n darii moto lagbegb Wema Bank ni Station roodu nilu Osogbo.
A gbo pe Femi wa moto lona ti ko ba ofin mu lo je ki okunrin olopa yii, Oladele Femi da a duro lati fi pampe ofin mu un sugbon apo ibinu dereba yii nigbese olopa ohun bo si, bo si se sokale ninuu moto loun atawon oree re sina iya fun un.
Olufemi atawon oree re; Aremu Abiola eni odun mokandinlogbonati Bamigboye Adeola eni odun merinlelogbon la gbo pe leyin ti won na olopa yii pelu ese ni won tun mu okuta ti won si se e lese pupo.
Ojo kejidinlogun osu kejo odun yii la gbo pe isele ohun sele ni nnkan aago marun irole.
Opelope awon eeyan ti won wa nitosi ni won je ki won ri awon meteeta mu, ti won si dero ile ejo.
Agbenuso funleese olopa lori oro naa, Sajenti Sunday Ajayi so funle ejo pe awon olujejo meteeta ohun tun fa aso okunrin olopa naa ya lasiko ti won n dijo dana iya fun un.
Esun marun otooto to ni ijiya labe ofin iwa odaran orileede yii ni won fi kan awon olujejo meteeta lojo naa sugbon awon meteeta ni awon ko jebi awon esun naa.
Bakan naa ni agbejoro won, Nnajite Okobie so ile ejo lati faaye beeli sile fun won niwon igba ti awon esun yen kii se eyi ti won ko le gba beeli re. O waa seleri pe won ko nii sa fun igbejo.
Ninu idajo re, Majistreeti Olubukola Olowolagba faaye beeli sile fawon olujejopelu egberun lona ogorun naira ati oniduro meji ni iye kannaa.
O ni awon oniduro yen gbodo fi iwe eri owo ori sisan won sile pelu foto won. Leyin naa lo sun igbejo siwaju di ojo keje osu kewa odun yii.

No comments:
Post a Comment