IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 22 September 2016

N'Ileefe, Olalekan ji foonu, odidi osu kan ni yoo lo lewon

Ile ejo majistreeti kan nilu Ileefe ti so omokunrin omo odun mokanlelogun kan, Abiodun Olalekan si ewon osu kan gbako tabi ko san faini egberun lona marun naira lori esun ole jija.
Ojo keje osu kesan odun yii la gbo pe Lekan wonuu yaara Nwabueze Onyinyechi to je omoleewe OAU lasiko ti iyen n foyin niwaju ita, o si ji foonu ITEL 1503 ti owoo re je egberun lona meedogun naira.
Ni nnkan aago mefa aabo irole ojo naa, gege bi agbenuso funleese olopa lori oro naa, Sajenti Ona Glory se so funle ejo, ni Lekan huwa naa lagbegbe Oroki nilu Modakeke.
Nigba ti owo te Lekan, awon araadugbo naa fiya je e bii kiku bii yiye, leyin naa ni won fa a le awon agbofinro lowo nibi to ti jewo pe loooto loun huwa naa.
Glory ni iwa ti olujejo hu ohun nijiya nla labe ofin iwa odaran tipinle Osun. Leyin eyi ni olujejo so pe loooto lohun jebi esun ole jija ti won fi kan oun, o si bebe pe ki ile ejo siju aanu wo oun.
Nigba to n gbe idajo re kale lori oro Olalekan, Majistreeti Risikat Olayemi foju buruku wo iwa ti Lekan hu, o ni asiko to ye ko maa se nnkan to nitumo fun aye araa re ko baa le ni ojoowaju to logo lo n jale kaakiri.
O ni ewon odun meje meje ni idajo esun kookan ti won fi kan olujejo sugbon nitori pe awon eeyan ti sedajo fun un funraawon ti won s ti da apa sii lara loun se din ijiya re ku.
O ni ki olujejo loo fi aso penpe roko oba fun odidi ogbonjo tii se osu kan tabi ko san faini egberun lona marun naira.

No comments:

Post a Comment