IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 7 September 2016

N'Ileefe, Sule ji okada Raufu; ibi to ti n wa eni ti yoo ra lowo ti te e

Ko si aniani nibe, ogba ewon ni omokunrin eni odun meedogbon kan, Afeez Suleiman yoo ti sodun ileya to n bo yii, koda, nnkan bii odun meji ni yoo lo nibe.
Esun ti won fi kan Sule ni o ji okada kan labule Bolorunduro nijoba ibile Guusu Ife nipinle Osun.
Ojo kejo osu kejo odun yii ni won lo ji okada TVS naa eleyii to je ti Ogbeni Adeniyi Raufu ti owo re to egberun lona aadoje o le meta naira.
Leyin ti Sule ji okada naa la gbo pe o loo gbe pamo si agbegbe Temidire nilu Ileefe, to si bere sii wa eni ti yoo ra a sugbon awon ti won mo pe kii se Sule lo ni okada ohun ni won ta awon olopa lolobo ti owo fi te e.
Ko je kawon olopa se wahala pupo to fi jewo pe loooto eru eleru ni okada naa, leyin iwadi ni won taari re sile ejo lose to koja.
Gege bi agbenuso funleese olopa lori oro naa, Inspekito Emmanuel Abdullahi se so funle ejo, o ni iwa ti Sule hu ohun lodi si ofin iwa odaran tipinle Osun, bee lo si ni ijiya pupo.
Bo tile je pe Sule so pe oun jebi esun ti won fi kan an, adajo majistreeti ohun, Olalekan Ijiyode ni irisi olujejo fidii esun idite ati ole jija ti won fi kan an mule.
Ijiyode ni didarijin Sule yoo buru lopolopo fun awujo wa, idi niyii to fi pase pe ki olujejo ohun maa lo sogba ewon mejidinlogun fun esun kookan laifaaye faini sile, sugbon o ni ko sewon naa leralera.

No comments:

Post a Comment