IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 13 September 2016

Orileede to ba fee ga gbodo samojuto awon odo- Ooni Ogunwusi


Ooni Ife Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi ti ni ko lee si igbega fun orileede ti ko ba naani awon odo ti won sese n dide bo, bee ni yoo si nira fun iru orileede bee lati wa lalaafia ti awon odo inu re ko ba nireti kikun nibe.
Oba alade yii ni nitori idi eyi loun se pinnu latigba ti Olorun ti fun oun lanfaani lati de ipo to wa pe idagbasoke awon odo ni yoo je akooko ninu ohunkohun toun ba fee maa se. O ni eleyii si ti mu ki iwa ipa ati jagidijagan dinku lopolopo ninu ileefe latigba toun ti de.
Ooni Ogunwusi, eni ti oludari feto iroyin re, Moses Olafare gbenuso fun salaye pe owo to ba dile lesu maa n be lowe, ati pe aibale okan to n sele lawon apaabikan lorileede yii ko seyin bi ko se si amojuto to peye fawon odo.
O ni lara ona lati mu kawon odo raaye fun ara won, ki won si mo pe awon naa je pataki lorileede yii loun se se agbekale eto ariya kan ti won pe ni "O ti see se Carnival 2016'  eleyii to ni yoo bere ayeye odun kan toun gun ori ite awon baba oun.
O fi kun oro re pe eeyan milioonu kan lawon n reti fun eto naa eleyii to ni yoo wa fun sisafihan awon oniruuru nnkan isenbaye to wa nilu Ileefe ati lati je kawon odo mo sii nipa asa ati ise ile Yoruba.
Ninu oro ti asoju awon ti won sagbekale ayeye naa, Desmond Buchi salaye pe eto olojo meta naa yoo bere lojo karun osu kejila titi di ojo keje osu naa, awon odo yoo sabewo sawon ibi isenbaye nilu Ilefe, bee ni awon olorin atawon osere tiata lorisiirisii yoo wa nibe.

No comments:

Post a Comment