Pelu oro ti awon agbofinro pelu ileese otelemuye orileede yii so laipe yii, o see se ki idibo gomina to ye ko waye nipinle Edo lojoo satide to n bo yii di sisun siwaju.
Awon agbofinro yii so pe awon ko lee fowosoya eto aabo to daju fun emi ati dukia awon oludibo nipinle Edo peluu ohun to wa nile bayii.
Idi niyii ti won fi n ke si ajo eleto idibo lati sun idibo naa siwaju sugbon awon ajo eleto idibo ko tii so ohunkohun lori oro naa nitori pe o ba won lojiji.


No comments:
Post a Comment