IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 5 October 2016

Danladi taku, o ni oun ko nii jawo loroo Saraki

Alaga igbimo to n ri si ejo to ba suyo lorii dukia awon osise ijoba atawon oloselu, Danladi Umar ti so pe ko see se fun oun lati jawo lori esun tijoba apapo fi kan aare ile igbimo asofin apapo ile yii, Dokita Bukola Saraki.
Lakooko ti igbejo waye laipe yii lori esun ti won fi kan Saraki ni agbejoro re so pe ki Danladi yowo ninu ejo naa nitori pe oun ko nigbagbo ninu adajo naa ati pe yoo sojoro lopin igbejo.
Sugbon Danladi ti so laipe yii pe oun ko lee yowo ninu ejo naa nitori pe igbimo naa ko lee wa laini alaga gege bo se wa ninu ofin to gbe e kale.

No comments:

Post a Comment