Tolulope Emmanuel, Osogbo
Timothy Adeniji, omo odun mokandinlogbon to ji okada nilu Ileefe ladajo ti ju sewon ose mefa bayii.
Inspekito Emmanuel Abdullahi to soju ileese olopa lori esun naa salaye funle ejo pe ojo keta osu kokanla odun yii ni Timothy yo n gbe lagbegbe Otutu nilu Ileefe huwa naa.
O ni ni nnkan aago marun aabo idaji ni Timothy ji okada Jincheng alawo buluu kan to ni nomba QD 721 FFE to si je ti Victor Odugade.
O ni iye owo okada naa to egberun lona aadorin naira. Ati pe iwa to hu ohun lodi, bee lo si nijiya labe ofin iwa odaran tipinle Osun.
Leyin ti won ka esun ole jija ti won fi kan an sii leti, o ni oun jebi.
Ninu idajo re, Majistreeti agba, Risikat Olayemi pase pe ki won loo fi olujejo pamo sogba ewon fun ose mefa gbako pelu ise asekara.
O waa faaye faini egberun lona marun sile fun Timothy.

No comments:
Post a Comment