IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 14 November 2017

Adajo soro kobakungbe si agbejoro n'Ileefe nitori Elugbemi Ijebu

Tolulope Emmanuel, Osogbo

Ile ejo majisteeti kan nilu Ileefe nipinle Osun gbona janjan lojoo Fraide to koja nigba ti adajo ibe, Olalekan Ijiyode gboju aagan si agbejoro to waa gbenuso fun afurasi kan nibe.

Ejo meta otooto ni afurasi naa, Tajudeen Elugbemi topo eeyan mo si Ijebu ni niwaju adajo Ijiyode lojo naa, agbejoro Ben Adirieje lo si waa soju e lona meteeta.

Idi niyii ti Ijiyode fi binu, o ni ko ye kawon agbejoro maa gbase lowo awon oniwa ibaje lati dinwo jagidijagan ku lawujo wa.

Ijiyode ni oniwahala, oyun ninu egungun awon araalu ni Ijebu, o si je iyalenu fun oun lati ri pe agbejoro kankan pinnu lati duro fun un ni kootu.

O ni ko seni ti ko mo Ijebu, enikeni to ba si ti foju kan an ni won maa n mo pe awon ti foju kan wahala ati idaamu. O ni o ye kawon loya mo iru odaran ti won yoo ma tele lo si kootu dipo ki won maa ja fun owo ti yoo wole sapo won.

Agbejoro naa, Adirieje waa seleri lati dekun ninu ejo naa.

Ko too di asiko ye ni Sajenti Sunday Osanyintuyi ti so pe Ijebu atawon ore re da agbegbe Ilare ru lojo keedogun osu kesan odun yii.

O ni se ni Ijebu atawon iyoku re da hilahilo sokan awon eeyan agbegbe ohun lojo naa nigba ti won n mu ada, aake, igo, igi ati bee bee lo kaakiri.

Ninu ejo miin, won fi esun merin otooto to nii se pelu igbimopo huwa buburu, didunkoko mo emi eni, ole jija ati ikoluni kan Ijebu eni odun mokanlelogoji.

Osanyintuyi ni  nnkan aago mejo aaro ojo keje osu keji odun yii ni Ijebu atawon akeegbe re huwa naa lagbegbe Iredunmi nilu Ileefe.

O ni se ni won loo ka Lamidi Abiola, Ayobami Kilowoda ati enikan mole pelu ada ati afoku igo.

Osanyintuyj ni Ijebu gba aago owo, oruka owo ati egberun lona ogota naira eleyii to mu ki apapo nnkan naa je egberun lona metadinlaadorun naira lowoo Kilowoba leyin ti won na an bii kiku bii yiye.

Ninu ejo keta ni won ni Ijebu ti fiya je okunrin kan toruko re n je Damilola Owoyori lagbegbe Akui nilu Ileefe lojo keje osu kokanla ni nnkan aago mejo aabo ale.

Osanyintuyi ni ada ati okuta ni Ijebu koko fi n le Damilola kaakiri ojuutiti lojo naa, nigba to mu un lo waa fiya je, to si tun fi okuta ba gbogbo enu e je.

Gbogbo esun yii ni Ijebu so pe oun ko jebi won, bee lagbejoro re, Adirieje naa n so pe kile ejo faaye beeli sile fun un pelu ileri pe ko nii salo fun igbejo.

Adajo Ijiyode waa pase pe ki won loo fi Ijebu pamo sogba ewon titi ti igbejo yoo fi waye lorii beeli re.

O waa sun igbejo sinu osu kinni ati osu keji odun to n bo.

No comments:

Post a Comment