IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 15 November 2017

E gbo idi tawon Soja fi gbajoba lorileede Zimbabwe


Alukoro ileese ologun lorileede Zimbabwe, Major General SB Moyo ti so pe lati kapa awon odaran ti won rogba yi ijoba Aare Robert Mugabe ka lorileede naa lawon se gbajoba laaro oni.

Wakati die seyin lawon soja gbajoba lorileede naa, won gba gbogbo ileese igbohunsafefe, bee ni won di ona to koja sile ijoba pa.

Sugbon Moyo ni igbese naa ko nii se pelu iditegbajoba rara bikose lati yo awon eeyan kuro ninu iya ati inira to n koju won.

O ni awon jegudujera kan ni won wa ninu ijoba Mugabe eleyii ti igbese won gbogbo n fi ara ni awon araalu, ati pe ni kete tawon ba ti pale won mo tan ni ohun gbogbo yoo bo sipo lorileede ohun.

Moyo waa seleri pe aabo to daju wa fun Aare Mugabe atidile re, bakan naa lo ro awon odo lati mase faaye gba enikeni lati lo won tako ohun to.n sele lowo lorileede naa nitori awon ni ogo orileede.

No comments:

Post a Comment