Tolulope Emmanuel, Osogbo
Gege bi ilu Ede nipinle Osun yoo se maa gbalejo eto Abiye Convention lose yii, Ajihinrere Olanrewaju Blessing ti fi da gbogbo awon to n n bo kaakiri agbaye loju pe ise ami ati ise iyanu, eleyi ti won ko tii ni iriri re ri yoo sele nibe.
Blessing, eni to je okan lara awon olupolongo Abiye Convention salaye pe ojoo Monde, ojo ketala si ojoo Fraide, ojo ketadinlogun osu kokanla odun yii ni ipago agbara naa yoo waye ni Ori Oke Baba Abiye lagbegbe Alaasan nilu Ede.
O ni eto aabo to nipon wa nile fun emi ati dukia gbogbo awon olukopa patapata.
Lara awon iranse Olorun ti yoo sise iranse nibe ni Woli Timothy Funso Akande atiyawo won, Mama Bola Are atawon miin.
Ajihinrere yii fi kun oro re pe aago kan osan ojoo Fraide ni adura pataki yoo wa fun gbogbo awon to n woju Olorun fun omo.
O waa ro gbogbo awon eeyan, laika ti esin won si, lati ri ipago Abiye ti odun yii gege bi anfani nla ti ko gbodo fo won ru.

No comments:
Post a Comment