IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 12 November 2017

Lasun Yusuff ati Aregbesola tako araa won lori oro ijoba ibile


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Igbakeji abenugan ile igbimo asofin apapo orileede yii, Onorebu Lasun Yusuff ti so pe awon gomina alajebanu ti won ko fe idagbasoke fun awon eeyan esekuku ni won lodi si igbese eleyii to le mu kawon ijoba ibile da duro.

Eleyii tako oro ti gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola n tenumo pe awon ti won ko fe isokan orileede yii ni won n polongo pe kawon ijoba ibile da duro.

Sugbon Onorebu Lasun ni se ni awon gomina ti won n tako igbese naa fee ma fiya je awon ti won wa nijoba ibile, eleyii ti ko dara to fun aseyori ijoba tiwantiwa lorileede yii.

O ni lati le je kawon eeyan mo iha toun ko si oro naa nigbimo ile to n satunse siwe ofin ile yii, ninu eyi toun ti je okan lara awon alaga se tete buwolu ofin to n pe fun idaduro ijoba ibile.

O fi kun oro re pe lowolowo bayii, ko si ijoba ibile kankan lorileede yii pelu bi awon gomina se ko ijoba ibile si apo, ti idagbasoke to nipon ko si si lesekuku.

Ni ti Gomina Aregbesola, tijoba ipinle ko ba mojuto awon iwolewode awon ijoba ibile, o le ma si idagbasoke to peye to lesekuku.

No comments:

Post a Comment