IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 15 November 2017

Lori afikun owo ileewe UNIOSUN, egbe ORA fi ejo Aregbesola sun ile igbimo asofin



Tolulope Emmanuel, Osogbo

Egbe Osun Renewal Agenda (ORA) ti won tun n pe araa won ni Akinbade's Ambassador ti ke si ile igbimo asofin ipinle Osun lati mase kawo gbera lori afikun ti Gomina Aregbesola mu ba owo ileewe UNIOSUN.

Ninu leta kan ti egbe ORA ko si awon asofin naa lojo kesan osu kokanla odun yii ni won ti salaye pe kii se iru asiko ti iya nje awon osise ijoba ipinle Osun lo ye ki Aregbesola tun di eru wuwo le awon obi ti won n tiraka lati ran awon omo nileewe ohun.

Alakoso egbe ORA, Arakunrin Omotunde Stephen Adekunle so ninu leta ohun pe ara ojuse ile igbimo asofin ni lati da si awon igbese ijoba to ba le mu inira ba awon araalu.

O ni bo tile je pe se ni awon asofin naa se bii eni pe bijoba se mu afikun ba owo ileewe naa ko kan awon, sibe, gege bii abiyamo tooto, o ye ki won saanu awon araalu, ki won ba Aregbesola soro nibi to ti maa n gbo, ko si din owo ileewe naa.

No comments:

Post a Comment