IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 15 November 2017

Ni Modakeke, awon olode meji fisee won jafara, lole ba fo soobu ti won n so


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Dada Ajewole ati Sikiru Olasesan ti won n so agbegbe Adeboye nilu Modakeke ni won ti foju bale ejo majistreeti ilu naa bayii lori esun pe won gbojege lenu isee ti won gba won fun.

Omo ogun odun ni Dada nigba ti Sikiru je omo odun merinlelogun. Esun meji otooto to nii se pelu fifi ise jafara ati fifaaye gba ole lati fo soobu ni won fi kan awon mejeeji.

Gege bi agbejoro funleese olopa lori esun naa, Sajenti Ona Glory se wi, ojo kesan osu kewa odun yii nisele naa sele, nigba ti awon ole loo fo soobu meji lagbegbe ti awon olode naa n so ni nnkan aago meji si marun idaji.

Glory ni awon ole fo soobu obinrin kan to n je Mujidat Babatunde ati Owowumi Akinyemi lojo naa nipase aijafafa won.

O fi kun oro re pe apapo owo oja ti won ko ninu soobu mejeeji je egberun lona ogorun o le marun (#104, 300).

Agbejoro fawon olujejo, Victor Arojo rawo ebe sile ejo lati faaye beeli sile fun olujejo. O ni o setan lati fi oniduro to kunju osunwon sile ati pe igbakuugba to ba ti lejo nile ejo ni yoo maa wa.

Adajo majistreeti naa, Bose Awosan ninu idajo re gba beeli olujejo kookan pelu egberun lona meedogbon naira ati oniduro kookan ni iye kannaa.

O ni awon oniduro naa gbodo maa gbe lagbegbe ile ejo ti won si ni ise gidi lowo.

Leyin eyi lo waa sun igbejo siwaju di ojo keedogun osu kokanla odun yii.

No comments:

Post a Comment