IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 16 November 2017

Nitori owo-ori, awon OPC fiya je Akano, omoose Aregbesola


Tolulope Emmanuel, Osogbo
Ori lo ko oludamoran pataki fun Gomina Aregbesola lori oro owo ori ati ipawowole labenu, Barista Gbenga Akano yo loni nigba tawon omo egbe OPC koluu lenu ise re.

Ileese Dangote Quarry la gbo pe Akano atawon osise ileese IRS lo lati beere idi ti won ko fi sanwo ori latigba ti won ti bere ise nileese naa.

Owo ohun la gbo pe o ti to bilioonu lona kan ataabo naira, idi si niyii ti won fi pinnu lati loo ba won lagbegbe Ajebamdele nijoba ibile Ayedaade tileese ohun wa.

Sugbon bi won se debe, se lawon omo egbe OPC ti won to ogbon fon jade, loro ba di isu ata yan an yan an.

Leyin opolopo wakati ti oro naa role die ni Akano pase pe ki won ti ileese naa pa tii digba ti won ba san gbese ti won je ijoba.

No comments:

Post a Comment