IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 16 November 2017

Osun 2018: Bisi Akande satileyin fawon eeyan Iwo-oorun Osun, lo ba ni ki Lasun loo sinmi agbaja




Tolulope Emmanuel, Osogbo

Alaga apapo fegbe oselu APC lorileede yii nigba kan, Oloye Adebisi Akande ti ni ti egbe naa ko ba fee se ojusaju nipinle Osun, ekun Iwo-oorun ni eni ti yoo di gomina lodun to n bo gbodo ti wa.

Akande, eni to ti figba kan je gomina nipinle Osun salaye pe yoo je iwa anikanjopon ati aisedajo ododo ti enikeni ba n gbero lati dupo naa latibikibi yato si agbegbe ohun.

Lasiko ti awon adari egbe kan ti won pe ni Osun New Era Group (One-G) sabewo sodo re ni Baba Akande soro yii.

O ni latigba idasile ipinle Osun, ekun Iwo-Oorun nikan ni ko tii se gomina yato si olosumejilelogun ti Oloogbe Isiaka Adeleke se. O ni ekun Aaringbungbun ati Ila-oorun ti se, nitori naa, ekun Iwo-oorun ni eni ti yoo gbapo lowo Aregbesola ti gbodo wa.

Adebisi Akande waa ro awon eeyan agbegbe naa lati se araa won losusu owo, ki won sise takuntakun lati le gbe oludije to kunju osunwon, ti gbogbo aye yoo si tewo gba sile lodun to n bo.

Adari egbe One-G, Comreedi Rasaq Alarape waa dupe lowo Oloye Akande fun atileyin to n se funjoba Aare Buhari eleyii to ni o ti so eso rere pupo lorileede yii.

Bakan naa lo yin baba naa lawo fun bo se maa n duro nidi otito paapa eleyii to tun so nipa ibi ti gomina egbe APC yoo ti wa lodun to n bo. O ni awon ko nii kaare nipa tita gbogbo awon eeyan ipinle Osun ji lori idi ti ipo naa fi to si awon eeyan ekun Iwo-Oorun Osun.

No comments:

Post a Comment