Tolulope Emmanuel, Osogbo
Egbe akoroyin ere idaraya nipinle Osun, Sports Writers Association ti kede ojo keedogbon osu kinni odun 2018 gege bii ojo ti won yoo dibo yan awon oloye egbe tuntun.
Gege bi alaga egbe naa lowolowo, Ogbeni Adeyemi Aboderin se so, awon ti won ba yan ohun ni won yoo tuko egbe SWAN l'Osun fun odun meta to n bo.
Osu to n bo ni won yoo gbe awon igbimo ti won yoo tuko idibo naa sile.
Awon ipo ti won yoo dibo si ni ipo alaga, igbakeji alaga, akowe, igbakeji akowe, akowe owo, akapo.

No comments:
Post a Comment