Tolulope Emmanuel, Osogbo
Onorebu Olasunkanmi Yusuff tii se igbakeji abenugan ile igbimo asofin apapo orileede yii ti fi owo mejeeji soya pe oun loun yoo je gomina ipinle Osun lodun to n bo.
Lasun, eni to n soju awon eeyan Irepodun, Olorunda, Orolu ati Osogbo nile igbimo asofin apapo so pe o da oun loju, kii sii se oro asoje pe oun yoo gba ipo naa ni kete ti Gomina Aregbesola ba ti kuro nibe.
Nibi ayeye Ilobu Day ti odun yii eleyii to waye lopin ose to koja ni asofin yii ti ni oun kii du ipo kankan ati pe eyi toun ba ti jade lati du, o maa n bo si oun lowo laise laala ni.
Leyin to ki Onorebu Biyi Odunlade to sojuu Gomina Aregbesola nibi eto naa lo ni " Ore mi ni gomina, yato si oro oselu, opolopo nnkan lo tun pa wa po. A pe gomina lodun to koja, ko wa, a pe e lodun yii, o ran eeyan wa, lodun to n bo, oun gan an gan lo maa joko nibi ti maa si joko legbe e nitori mo ti maa di gomina ipinle Osun nigba naa nitori won ti so fun mi pe emi ni maa gbapo lowo re".
Lasiko ti oba ilu naa Oba Ashiru Olatoye n soro, o ro Onorebu Lasun lati maa se suru, o ni ipo agba lo wa, ko gbodo maa binu si gbogbo nnkan nitori pe Olorun nikan lo n feeyan sipo laye.
Monday, 13 November 2017
Home
/
iroyin
/
iroyin-agbegbe
/
iroyin-oselu
/
Won ti so fun mi pe emi ni maa gbapo lowo Aregbesola - Lasun Yusuff
Won ti so fun mi pe emi ni maa gbapo lowo Aregbesola - Lasun Yusuff
Tags
# iroyin
# iroyin-agbegbe
.Njeetigbo
.
iroyin-oselu
Labels:
iroyin,
iroyin-agbegbe,
iroyin-oselu
Subscribe to:
Post Comments (Atom)

No comments:
Post a Comment