IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 28 September 2017

Asiko ti to fun mi lati yo Olubadan, sugbon...... Ajimobi

Omotola Abe, Ogbomoso

Gomina ipinle Oyo, Seneto Abiola Ajimobi ti so pe osunwon ese Olubadan tile Ibadan, Oba Saliu Adetunji ti kun niwaju oun sugbon awon nnkan kan lo n ka oun lowo ko lati yo baba naa loye.
Ajimobi ni oun ti ni gbogbo akosile to to lati fi gbe igbese to le lori Oba naa latari awon iwa to n hu lenu ojometa yii sugbon oun rii bii baba oun loun ko se mo nnkan toun yoo se fun un.
Lasiko ti gomina n sepade pelu die lara awon baale to sese yan sipo oba lo ti salaye pe ipo oun gege bii gomina ipinle Oyo ti so oun di asiwaju atoba atijoye pelu awon araalu to wa nipinle naa.
O ni toun ba fee lo ipo oun ni o ye koun ti gbe igbese to le lori oro Oba Adetunji sugbon oun ko le se bee nitori baba ati oludamoran ni Oba naa je foun.
Gomina Ajimobi ni bi awon agbegbon se ya wo aafin Olubadan lojo die seyin ko seyin ise owo awon oloselu kan ti won fee ba ipinle Oyo je mo oun lori.
O fi kun oro re pe ijoba oun ko nii laju sile lati maa woran kiwa ibaje ati aibowo fun ofin si maa tesiwaju.

No comments:

Post a Comment