Tolulope Emmanuel
Oludamoran pataki fun gomina Aregbesola lori oro asa atawon ibudo nnkan isembaye, Taiwo Oluga ti so pe laipe nijoba ipinle Osun yoo gboju kuro ninu owo to n wole latodo ijoba apapo latari owo nla ti yoo maa wole latipase awon ibudo nnkan isembaye nipinle Osun.
Oluga ni idi niyii tijoba Aregbesola fi n sa gbogbo ipa lati rii pe agbelaruge de ba awon ibudo naa kaakiri ipinle Osun.
Lasiko ayeye ojoo nnkan isembaye lagbaye eleyii to waye nilu Gbongan nijoba ibile Ayedaade lo ti soro yii.
O ni lara ona kan gboogi lati fopin si airise ati ailowo lowo laarin awon araalu ni gbigbaruku ti awon ibudo asa ti Eledua fi jinnki ipinle kookan.
Idi niyii, gege bi Oluga se so, tijoba Gomina Aregbesola fi mu ipese ona to yo kululu ati ipese awon nnkan amayederun sawon ilu ati agbegbe tawon nnkan isembaye wa nipinle Osun lati le je ki owo ti yoo maa wole latibe tun rugogo sii.
Oluga waa ro awon eeyan ipinle Osun lati fowosowopo pelu Aregbesola ki erongba re le wa simuse.
No comments:
Post a Comment