Ojo buruku gbaa logbonjo osu keje odun yii je fawon molebi omobinrin eni odun mokanlelogun kan, Aminat Abiodun, ojo yii lawon kan fipa ba omo naa sun, ti ko si je ara aye, bee ni ko je ero orun latigba naa.
Nnkan aago mejo ale la gbo pe Ademola Adeleye to je omo odun merinlelogoji ati Adam Mohammed eni odun merinlelogun fipa ba lo po lagbegbe Balogun Aguro nilu Osogbo.
Leyin ti ojuu Aminat wale tan lo salaye ohun to sele fawon obi e sugbon o so fun won pe o dabi eni pe won fi nnkan ba oun lo po ni.
Latigba naa ni Aminat ti n ru to si n gbe, o ranti ibi tisele naa ti sele, awon olopa si loo gbe awon mejeeji, bee la gbo pe awon eeyan yii jewo nigba ti owo iya te won lago olopa.
Won ko won wa so kootu lori esun mefa otooto, agbejoro awon olopa, Taiwo Adegoke ni Olorun nikan lo ku to le ra emi Aminat pada.
Agbejoro awon olujejo, Dauda Oyewale ro ile ejo lati faaye beeli sile fun won.
Majistreeti Adenike Olowolagba pase pe ki won loo fi awon olujejo pamo sogba ewon ilu Ilesa titi di ojo kinni osu kokanla odun yii tigbejo yoo tun waye lori oroo won.
Wednesday, 27 September 2017
Home
/
iroyin
/
isele-nla
/
Awon molebi Aminat tokunrin meji fipa ba lo l'Osogbo pariwo pe bo se n ru lo n gbe o
Awon molebi Aminat tokunrin meji fipa ba lo l'Osogbo pariwo pe bo se n ru lo n gbe o
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
Oye kiya he won dada, iwa odaran ati iwa odaju gba ni won hu
ReplyDelete