IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 27 September 2017

Semiu jewo! "Feeki ma lojubo temi, mo kan fi n lu awon eeyan nijibiti lasan ni"


Tolulope Emmanuel, Osogbo 
Odediran Semiu, eni odun mejilelogoji lo ti jewo pe ko sagbara kankan ninu yaara kekere kan toun n lo bii ojubo ninu ile oun, o ni abamoda ni gbogbo e. 
Semiu lowo awon olopa te nilu Apomu nipinle Osun lose to koja, ti won si ba opolopo nnkan aderubani ninuu ile re. 
Nigba tawon oniroyin n beere oro lowo Semiu, o ni ofuutufeete ni gbogbo nnkan ti won ri ninu ile oun, ko si agbara kankan nibe. 
Nipa bo se je pe ise jibiti lo yan laayo ni tie, Semiu ni adaniloro kan lo fagbara ko oun. 
O ni okunrin babalawo kan lo lu oun ni jibiti nilu Eko toun naa fi sa wa sipinle Osun lati waa gbesan iwa okunrin naa lara awon alaimokan eeyan. 
Semiu ni boun se de Apomu loun naa ko awon ere lasan jo toun si se oniruuru eso si won lara kawon eeyan le ro pe nnkan gidi kan ni. 
O fi kun oro re pe oun si ti n fi kinni ohun jeun werewere tori gbogbonise loun pe ojubo oun naa ko too di pe owo awon olopa ba oun. 
O ni boun se n soogun iwosan loun tun n soogun awure ati ti awon to n wa omo fawon eeyan ti won n wa sodo oun, sugbon to je pe arumoje lasan ni. 
Nigba to n soro, komisanna olopa nipinle Osun, Olafimihan Adeoye so pe opolopo ere lawon ba lojubo Semiu, bee ni won tun ba orisiirisi owo ile okeere to je ayederu ninu ile e. 
Adeoye waa ro awon araalu lati kiyesara lodo awon ayederu babalawo ti won kan n lu won ni jibiti lailoogun kankan. 
O ni ni kete tiwadi ba ti pari ni Semiu yoo foju bale ejo.

No comments:

Post a Comment