IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 27 September 2017

Ko seni to le le mi ninu egbe oselu APC - Diekola

Tolulope Emmanuel, Osogbo
Okan pataki lara awon omo egbe oselu APC nipinle Osun, Alhaji Fatai Diekola ti so pe ko senikankan to le le oun kuro ninu egbe naa bo tile wu ki won gbogun to. 
Lasiko ayeye ayajo ojoobi odun kokanlelogota ti won se fun Diekola ni Osun civil service club laipe yii lo ti so pe digbi loun wa ninu egbe naa ti enikeni ko si le  fowo ro oun seyin. 
Diekola lawon eeyan gbagbo pe wahala ti wa laarin re pelu Gomina Aregbesola ni nnkan osu die seyin. 
O waa so siwaju pe abamo ni bi won se n gba awon gomina laaye lati maa lo saa meji nitori iriri ti fihan pe iwakiwa ni won maa n hu ni saa keji. 
Diekola, eni to ti figba kan je alaga ijoba ibile Osogbo ni akooko ti to lati gbogunti lilo awon ti won ko gbe laarin ilu gege bii gomina nitori won ko nii mo ibi ti bata ti n ta awon araalu lese. 

1 comment: