Adeola Tijani, Ibadan
Oro di bo o lo o ya lona laaro oni nigba tawon agbebon ti won je merin niye doju ibon ko aafin Olubadan tile Ibadan, Oba Saliu Adetunji lasiko ti oba naa n fi awon kan joye Mogaji ati Baale.
Nnkan aago mejila ku die la gbo pe awon agbebon naa de, won bere sii yinbon soke lakolako, bee ni won n pariwo pe eni to ba laya ko jade waa wo awon.
Koda, ori lo ko awon oniroyin ti won wa niwaju aafin lasiko isele naa yo, bee ni won fibon dara si moto akowe tele funjoba ipinle Oyo, Sharafadeen Alli lara.
Odidi iseju mewa la gbo pe awon eeyan naa lo niwaju aafin Olubadan, leyin ti ko seni to da won lohun ni won forile ona Molete Popoyemoja.
Sugbon bi wahala naa se da jinnijinni bo awon ti won wa lagbegbe naa to, ayeye ifinijoye Mogaji ati Baale ohun ko dawoduro.
Iru iwa arifin bayi kodara rara, osi da mi loju le yio leyin
ReplyDeleteIru iwa arifin bayi kodara rara, osi da mi loju le yio leyin
ReplyDelete