IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 26 September 2017

Afise ma loro Gbenga yii o, adiye lo tun loo ji l'Osogbo, bee o sese tewon de ni

Tolulope Emmanuel 
Ileese olopa ipinle Osun ti wo omokunrin eni odun mejilelogbon kan lo siwaju ile ejo majistreeti ilu Osogbo lori esun ole jija.
Gbenga Daramola ni won fesun kan pe o ji adiye to je ti Saka Mojirade lojo ketalelogun osu kejo odun yii lagbegbe Balogun Biiro, Oke Baale nilu Osogbo ni nnkan aago marun aabo irole. 
Gbenga, eni ti won ni ko pe to sewon kan tan nilu Abuja ni yato si adiye yii, o tun ji aso omokekere, ofifo igo kooki ati foonu kan. Apapo owo nnkan to ji ohun si n lo bii egberun lona ogoji naira. 
Agbejoro awon olopa, Inspekito Rasaki Olayiwola salaye pe iwa olujejo nijiya labe ofin iwa odaran tipinle Osun, bee naa ni agbejoro olujejo, Nagite Okobie ro ile ejo lati faaye beeli sile fun un leyin to so pe oun ko jebi esun mereerin ti won fi kan an. 
Ninu idajo re, Majistreeti Fatimah Sodamade faaye beeli sile fun olujejo pelu egberun lona ogorun naira ati oniduro kan ni iye kannaa. 
O waa sun igbejo siwaju di ojo kerindinlogbon osu kewa odun yii. 

1 comment: