Abiodun Akanji, Ekiti
Agbarijopo egbe awon agbejoro obinrin lagbaye ti so pe awon ti setan lati fi ese ofin to oro okan lara awon omo ile igbimo asofin ipinle Ekiti, Onorebu Dare Pelemo lati so tenu e lori esun ti obinrin opo (widow) kan fi kan an.
Pelemo ni obinrin naa, Arabinrin Mercy Ilesanmi mu ejo re loo ba awon agbejoro ohun pe o fee fi tipatipa ba oun lasepo, koda, ibi oyan lo ti bere debii pe aso oun faya si meji leyin.
Ilesanmi ni adari omo ile to poju loun wa lo si ogba ile igbimo asofin ti Pelemo fi ri oun, to si huwa ainitiju naa soun.
Eni to wa ni eka eto idajo fun awon agbejoro obinrin, Kemi Atitebi salaye lori eto ileese redio Adaba FM nilu Ondo pe leyin igba tobinrin naa mu ejo waa ba awon, awon ko leta laimoye igba lati pe asofin ohun ki won le yanju oro naa nitubi nnubi, sugbon se lo fi gbigbo se alaigbo.
Idi niyen ti won fi ni o dabi eni pe ile ejo loro Onorebu to n soju awon eeyan Ekiti East 2 nile igbimo asofin ohun yoo yori si.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment