IROYIN YAJOYAJO

Friday, 10 November 2017

Haba! Kansu renti ile lowoo Oloye Obasanjo, e wo iye ti baba fee maa gba lodun


Ile olojule marundinlogbon to je ti aare ana lorileede yii, Oloye Olusegun Obasanjo lo ti fi renti fawon ijoba ibile kan nipinle Ogun bayii.

Ile naa to wa ni abule Ibogun ti Obasanjo ti wa nijoba ibile Coker-Ibogun Local Council Development Area (LCDA) fe maa lo gege bii sekiteriati won.

Sugbon iyalenu lo je lasiko ti alaga ijoba ibile agbegbe naa, Juwon Gbadebo n so fungbimo ile asofin ipinle naa lori oro ijoba ibile ti won sabewo si Ibogun pe naira mewa pere ni Obasanjo ni oun yoo maa gba lodoodun lori gbogbo ile ohun.

Gbadebo ni yato si ile naa to duro daada, awon nnkan bii omi, ile iyagbe, ero amunawa ati bee bee lo ni Obasanjo gbe sibe.

Asaaju igbimo naa, Olusola Sonuga waa ro awon osise kansu naa lati lo ile naa daradara, ki won si gbajumo ona lati pa owo wole labenu fundagbasoke agbegbe naa.

No comments:

Post a Comment