Tolulope Emmanuel, Osogbo
Komisanna feto isuna nipinle Osun, Ogbeni Bola Oyebamiji ti ni loooto nijoba Gomina Aregbesola ti je obitibiti gbese kaakiri sugbon o tona kawon eeyan gbosuba fun un lori awon nnkan to lo owo naa le lori.
Oyebamiji so nilu Osogbo pe kii se iye gbese to wa nile lo ye kawon eeyan maa wo bikose atubotan awon nnkan tijoba je gbese le lori.
O ni Aregbesola ye leni ti gbogbo araalu yoo maa yin fun bo se ronu pe awon ise akanse loun yoo maa na owo toun n ya le lori nitori pe ere nla nigbese naa yoo mu wa funpinle Osun lojo iwaju.
O ni olopolo pipe ni Aregbesola, eni to maa n ronu koja ere isinsinyii, idi niyii to fi n na awon owo naa lorii oju-ona, kiko ileewe nlanla, papako ofurufu MKO Abiola ati amojuto ise agbe ki ojo ola ipinle Osun atawon eeyan re le dara.
Oyebamiji, eni to to figba kan je adari nileese to je tijoba Osun ti won n pe ni Osun State Investment Company Limited, OSICOL fi kun oro re pe nigba tawon ara ile okeere sagbeyewo iye gbese tijoba je pelu awon ise nlanla to wa nile, se ni won n gbe osuba kara fun Gomina Aregbesola.
O ni saare (hectares) ile to to egbeta ni ileese OSICOL ti fi dako ogede bayii, eleyii to ni aseyori nla kan ni pelu.
O waa ro toloritelemu nipinle Osun lati tubo maa fi adura ranjoba lowo fun idagbasoke ipinle Osun.
No comments:
Post a Comment