Ojo itiju gbaa ni ana je fun gomina ipinle Benue, Samuel Ortom pelu bi alufa ijo Katoliiki kan, Reverend Father Aswe se yeeye re laarin ijo.
Isin idupe kan ti won gbe kale loruko gomina ipinle naa tele, George Akume la gbo pe Ortom lo fun ti abuku naa fi kan an.
Bi won se gbe ero gbohungbohun le gomina, eni to je awon osise ipinle re lowo osu repete, lowo lati soro la gbo pe alufaa naa dide, o bo siwaju, o si kede pe ibi igbalejo nikan ni gomina Ortom ti le soro nitori pe ile mimo ni soosi je.
Alufaa yii ni inu soosi kii se ibi tenikeni ti le maa paro, o ni ko lo maa paro re nigba to ba jade.
No comments:
Post a Comment