Ileese olopa ipinle Anambra ti n wa pasito ijo kan ti won fesun kan pe o fi ese lu iyawo re pa nitori ti iyen beere owo ti yoo fi dana lojo odun keresi.
Pasito Everitus, eni to ti feyinti nidi ise abesekubiiojo (boxer) la gbo pe lasiko ti iyawo re, Fidelia beere owo ti yoo fi dana lojo odun ni wahala be sile laarin won nilee won to wa lagbegbe Uli nijoba ibile Ihiala.
Kawon eeyan too mo nnkan to sele, iyawo ti daku lo rangbondan, ko si too di pe won dele iwosan lo ti jade laye.
Bi oko se ri nnkan to sele la gbo pe o ti juba ehoro ti won ko si tii ri latigba naa.
Sugbon awon odo agbegbe naa ya lo si ile ti Pasito Everitus ko si abule Amamputu, won si dana sun un.
No comments:
Post a Comment