IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 31 December 2017

Osun 2018: Ija nbo laarin Oloye Bisi Akande ati Asiwaju Tinubu



Tolulope Emmanuel, Osogbo

Arigbamu iroyin ti fidi e mule bayii pe wahala nla ti n fi dugbedugbe laarin eni to ti figba kan ri je adele alaga egbe oselu APC lorileede yii, Oloye Bisi Akande ati asiwaju ninu egbe naa, Bola Ahmed Tinubu.

Gege bi a se gbo, oro eni ti yoo gbapo gomina ipinle Osun lowoo Gomina Aregbesola lodun 2018 lo fee da wahala naa sile.

Losu bii meta seyin ni Oloye Akande so gbangba pe lati iha Iwo-oorun ipinle Osun ni enikeni ti yoo di gomina yoo ti wa ti egbe naa ba mo nnkan ti won n se.

Sugbon nibi ipade kan to waye nile Asiwaju Tinubu nilu Eko laipe yii la gbo pe Tinubu ti pase fun Gomina Aregbesola lati rii pe olori awon osise loofiisi gomina, iyen Alhaji Gboyega Oyetola lo di gomina.

Tinubu, gege bi a se gbo, so fun Aregbesola lati sa gbogbo ipa ati agbara re lati rii pe Oyetola lo gbapo lowo e.

Eleyii lo fa oniruuru oro iwuri ti Aregbesola n so nilee Oloye Akande lopin ose to koja nipa Oyetola.

A gbo pe se ni Baba Akande kan n wo Aregbesola bii fiimu nigba to n so pe Oyetola lo mu ijoba oun se awon aseyori toun se ati pe eni to to fise ogun ran lokunrin oloselu to wa lati aaringbungbun Osun ohun.

Bakan naa niwadi latodo awon ti won sunmo Oyetola naa fidi e mule pe ipo gomina ohun wu baba naa ati pe o nigbagbo pe ti Aregbesola ba se nnkan ti Tinubu ran an daada, didun losan yoo so fun oun.

Sugbon awon ti won sunmo Oloye Akande so pe ala ti ko lee se loro naa nitori pe ' Baba Akande kii duro nidi abosi, oun ti baba ti so yen gan an ni won a tele. Won mo pe Iwo oorun lo kan ni won se so nigba naa'.

Bakan naa ni awon omo egbe oselu APC ti won wa lati agbegbe Iwo oorun Osun ni yato si pe odo awon lo kan, awon asaaju egbe tun gbodo ronu si esin to kan daada ki won ma baa padanu nibi idibo naa.

No comments:

Post a Comment