IROYIN YAJOYAJO

Monday, 1 January 2018

Gbogbo oloselu gbodo mu igbayegbadun awon araalu lokunkundun - Oduoye


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Okan lara awon to n gbaradi lati dupo gomina ipinle Osun lodun yii, Dokita Kayode Oduoye ti ro gbogbo awon oloselu lati mu igbayegbadun awon oludibo lokunkundun ninu ohun gbogbo ti won ba n se.

Oduoye, eni to soro yii ninu oro ikinni odun tuntun to fi ranse salaye pe dipo ko won maa se ileri ti won ko lee mu se, se ni ki won kuku so nnkan to wa nikawo won lati se.

O ni ojuse ijoba to kunju osunwon ni lati mu ara tu awon araalu ti won dibo fun win, eleyii to ni ijoba to wa  bayii ko mojuto lodun to koja.

Super Kay, gege bi won tun se maa n pe e waa si awon araalu niye pe won ko gbodo dibo fun awon oloselu ti ko ba ti so nnkan to nitumo nipa igbayegbadun won ati ona to fee gba lati mu awon ileri naa se lasiko to ba n sepolongo ibo kaakiri.

Bee lo gbadura pe ki Olorun yan asiwaju ti yoo niberu Olorun fawon eeyan ipinle Osun ninu odun yii.


No comments:

Post a Comment