IROYIN YAJOYAJO

Monday, 1 January 2018

E gbagbe ijakule odun to koja, e wonu odun tuntun pelu ipinnu otun - Omooba Fadahunsi

 Tolulope Emmanuel, Osogbo

Asiwaju kan nipinle Osun, Omooba Ade Fadahunsi ti ro gbogbo awon eeyan ipinle Osun lati gbagbe awon ala won ti ko wa simuse lodun to koja pelu gbogbo awon ijakule ti won ba pade, ki won si gba pe ireti si n be fun won niwon igba ti emi si wa.

Ninu oro ikini ku odun tuntun eleyi ti akowe iroyin re, Sam Progress fowosi ni Omooba Fadahunsi ti ni loooto ni nnkan nira fawon omo orileede yii lodun to koja sugbon won ko gbodo so ireti nu rara.

Fadahunsi, eni to dije funpo seneto lati Ila-oorun Osun lodun 2015 gboriyin fun awon eeyan ipinle Osun fun ifarada won paapa lasiko ti ohun gbogbo duro daari fun awon osise ijoba.

Gege bo se wi, " mo ni imolara nnkan tawon eeyan wa koju paapa lodun to koja nitori pe gbogbo ireti wa wa ninu ijoba pelu awon osise ijoba, sugbon mo mo pe bekun pe dale kan, ayo nbo lowuro".

O waa ro awon araalu lati mo pe atelewo eni ko lee tanni je rara, o ni ki won mo pe ojo ola yoo dara, ki won nipinnu okan lati se aseyori si rere ninu ogbon atinuwa ti won ba dawole.


No comments:

Post a Comment